Bi o ba se igba eniyan won yio dari jin e lagbara olorun: ewe aanu, ewe orijin, ewe ooyo, ewe ajeofole, ao toju epo pupa die, ori die, adi die, ao gbe won sinu oorun lotooto ti won o fi yo tan. Ao gun gbogbo eroja yen papo pelu ose dudu ao wa kan die die ninu epo, ori ati adi yen si, ao po papo. Ofo re: ewe olusaanu loni ki e saanu mi, ewe orijin loni ki e foro temi jinmi, ewe ajeofole loni ki oran gbogbo o fomi ru, ooyo loni ki e maa yonu simi, bi epo ba foju kan oorun ti inu re yo ni, bi ori ba foju kan oorun ti inu re yo ni, bi adi ba foju kan oorun ti inu re yo ni.
No comments:
Post a Comment